Hymn 549: May the grace of Christ our Saviour

K’ore- ofe Krist’ Oluwa

  1. f K’ore-ọfẹ Krist’ Oluwa,
    Ifẹ́ Baba ailopin,
    Oju rere Ẹmí mimọ́,
    K’o t’oke ba sori wa.

  2. f Bayi l’a le wà ni ‘rẹpọ̀,
    Awa ati Oluwa:
    K’a si le ni ‘dapọ̀ didùn,
    At’ ayọ̀ t’ aiye kò ni.