Hymn 548: Saviour, again to Thy dear name we raise

Olugbala, a tun fe f’ohun kan

  1. f Olugbala, a tún fẹ f’ohun kan
    Yìn orukọ Rẹ k’a to tuka lọ;
    Ni ‘pari ‘sìn, a dide lati yìn:
    p A o si kunlẹ fun Ibukun Rẹ.

  2. mp F’alafia fun wa, b’a ti nre’le,
    cr Jẹ k’a pari ọjọ yi pẹlu Rẹ;
    Pa aiya wa mọ, si ṣọ ete wa,
    T’a fi pè orukọ Rẹ n’ile yi.

  3. mp F’alafia fun wa l’oru oni,
    cr Sọ okunkùn rẹ̀ d’imọlẹ fun wa;
    mf Ninu ewu, yọ ara ọmọ Rẹ,
    Okùn on ‘mọlẹ j’ọkanna fun Ọ.

  4. mp F’alafia fun wa lọj’ aiye wa,
    cr Rẹ̀ wa l’ẹkun, k’O si gbè wa ni ‘jà:
    mf ‘Gbat’ O ba si f’opin s’ijamu wa,
    p Pè wa, Baba, s’ọrun Alafia. Amin.