- mf Wá, Jesu fi ara han,
Wá, jẹ k’ ọkàn wa mọ̀ Ọ:
Wá, mu gbogb’ ọkàn gbona,
Wá, bukun wa k’a to lọ.
- Wá, f’aiya wa n’ isimi,
Wá, k’a d’ alabukunfun;
Wá, sọrọ̀ Alafia.
Wá, busi igbagbọ wa.
- f Wá, le ‘ṣiyemeji lọ,
Wá, kọ́ wa b’a ti bẹ̀bẹ;
Wá, fun ọkàn wa n’ ifẹ,
Wá, fa ọkàn wa soke.
- f Wá, sọ f’ ọkàn wa k’o yọ̀,
Wá, wipe, “’Wọ ni mo yàn;”
Wá, p’ awọn agbo Rẹ mọ,
Wá, sure f’ agutan Rẹ. Amin.