Hymn 544: Come, Thou Fount of every blessing

Wa, iwo Isun ibukun

  1. f Wá, iwọ Isun ibukun,
    Mu mi kọrin ore Rẹ:
    Odò anu ti nṣàn, titi
    Bère orin ‘yìn kikan.
    Oluwa, kọ́ mi l’orin na,
    T’ ogun ọrun nkọ loke;
    Jẹ ki nròhin iṣura na,
    Ti ifẹ Ọlọrun mi.

  2. mf Nihin l’a ràn mi lọwọ de,
    Mo gbe Ebenesar ro;
    cr Mo nreti nipa ‘nu’re Rẹ,
    Ki nde ‘le l’alafia.
    p L’ alejo ni Jesu wá mi,
    Gba mo ṣako lọ l’agbo,
    Lati yọ mi ninu ègbé,
    O f’ ẹ̀jẹ Rẹ̀ s’ ètutu.

  3. cr Nit’ or-ọfẹ, lojojumọ
    Ni ‘gbèse mi sì npọ̀ si;
    K’ore-ọfẹ yi já ẹ̀wọn
    Ti nṣe ‘dèna ọkàn mi,
    p Ki nṣako ṣa l’ ọkàn mi nfẹ,
    Ki nkọ̀ Jesu ti mo fẹ́:
    cr Olugbala, gbà aìya mi,
    Mu yẹ f’ agbala ọrun. Amin.