Hymn 543: Lord, dismiss us with Thy blessing;

Fi ibukun Re tu wa ka

  1. mf Fi Ibukun Rẹ tu wa ka,
    Fi ayọ kùn ọkàn wa;
    K’ olukuluku mọ̀ ‘fẹ Rẹ,
    K’a l’ayọ n’nu ore Rẹ:
    Tù wa lara, tù wa lara
    La aginju aiye ja.

  2. f Ọpẹ at’ iyìn l’ a nfun Ọ,
    Fun ihinrere ayọ̀;
    mf Jẹ ki eso igbala Rẹ
    Pọ̀ lọkàn at’ ìwa wa :
    cr Ki oju Rẹ, ki oju Rẹ
    Ma ba wa gbe titi lọ.

  3. p Njẹ, nigbat’ a ba sì pe wa
    Lati f’ aiye yi silẹ,
    cr K’ Angẹli gbe wa lọ sọrun,
    Layọ̀ ni k’a jipe na;
    f K’a si jọba, k’a sì jọba
    Pẹlu Kristi titi lai. Amin.