- K’ Ọlọrun ṣọ́ ọ, k’a tun pade !
Ki imọran Rẹ̀ẹgbe ọ ro,
K’o kà ọ mọ agutan Rẹ̀,
K’ Ọlọrun ṣọ́ ọ, k’a tun pade !
K’a pade … k’a pade !
K’a pade l’ ẹsẹ Jesu:
K’a pade … k’a pade !
K’ Ọlọrun ṣọ́ ọ, k’a tun pade !
- K’ Ọlọrun ṣọ́ ọ, k’a tun pade !
K’o f’ iyẹ Rẹ̀ dabòbò ọ,
K’o ma pèse fun aini rẹ,
K’ Ọlọrun ṣọ́ ọ, k’a tun pade !
K’a pade, &c.
- K’ Ọlọrun ṣọ́ ọ, k’a tun pade !
Nigbat’ ewu ba yi ọ ka,
K’ O f’ ọwọ ‘fẹ Rẹ̀ gba ọ mu,
K’ Ọlọrun ṣọ́ ọ, k’a tun pade !
K’a pade, &c.
- K’ Ọlọrun ṣọ́ ọ, k’a tun pade !
K’o fi ifẹ ràdọ bò ọ,
K’o pa oro iku fun ọ,
K’ Ọlọrun ṣọ́ ọ, k’a tun pade !
K’a pade … k’a pade !
K’a pade l’ ẹsẹ Jesu:
K’a pade … k’a pade !
K’ Ọlọrun ṣọ́ ọ, k’a tun pade. Amin.