- Lẹkan k’a to tuka,
Jẹ k’a yìn Oluwa !
Ki ọkàn at’ ahọn,
F’ iyin f’ orukọ Rẹ̀;
Jesu, ọrẹ ‘lẹṣẹ,
Ẹnit’ ọkàn wa nyìn;
Iyin Rẹ̀ kò lopin,
Ẹ yin titi lailai.
- N’nu Ọ̀rọ mimọ́ Rẹ̀,
L’ awa o ma dagba;
K’a ma mọ̀ Oluwa,
K’a ṣe eyi t’ a mọ̀.
Jesu ọrẹ ‘lẹṣẹ, &c. Amin.