Hymn 540: Accept my heart just as it is

Gb’ okan mi gege b’o ti ri

  1. mf Gb’ ọkàn mi gẹgẹ b’o ti ri,
    Tẹ itẹ Rẹ sibẹ;
    Ki nle fẹ Ọ ju aiye lọ,
    Ki mwà fun Ọ nikan.

  2. Pari ‘ṣẹ Rẹ Oluwa mi,
    Mu mi jẹ olotọ;
    K’ emi lè gbohun Rẹ, Jesu,
    Ti o kun fun ifẹ.

  3. Ohùn ti nkọ mi n’ifẹ Rẹ,
    Ti nsọ ‘hun ti mba ṣe;
    Ti ndoju tì mi, nigba nkò
    Ba tọpa ọ̀na Rẹ.

  4. Em’ iba ma ni ẹkọ́ yi,
    T’ o nti ọdọ Rẹ wá;
    Ki nkọ `tẹriba s’ohùn Rẹ,
    At’ ọ̀rọ isọyè. Amin.