Hymn 54: Hark, ’tis the watchman’s cry

Gbo ohun olore

  1. f Gbọ ohùn alore,
    Ji, ará, ji:
    Jesu ma fẹrẹ de,
    Ji, ará ji,
    mf Ọmọ oru ni ‘sùn,
    Ọmọ imọlẹ l’ẹnyin,
    Ti nyin l’ogo didán,
    f Ji, ará, ji.

  2. mf Sọ, f’ẹgbẹ́ t’o ti ji,
    Ará, ṣọra;
    Ase Jesu daju,
    Ará, ṣọra;
    p Ẹ ṣe b’oluṣọna
    N’ ilẹkun Oluwa nyin,
    Bi o tilẹ pẹ de,
    Ará, ṣọra.

  3. mf Gbọ ohùn Iriju,
    Ará, ṣiṣẹ;
    Iṣẹ na kárí wa,
    Ará, ṣiṣẹ;
    Ọgbà Oluwa wa,
    Kun fun ‘ṣẹ́ nigbagbogbo;
    Y’o si fun wa l’erè,
    Ará, ṣiṣẹ;

  4. mp Gb’ ohùn Oluwa wa,
    Ẹ gbadura;
    B’ ẹ fẹ k’inu Rẹ̀ dùn,
    Ẹ gbadura;
    p Ẹṣẹ mu ‘bẹru wà,
    Alaìlera si ni wa;
    Ni ijakadi nyin,
    Ẹ gbadura.

  5. f Kọ orin ikẹhin,
    Yìn, ará, yìn;
    cr Mimọ ni Oluwa,
    Yìn, ará, yìn;
    ff Kil’ o tun yẹ ahọn,
    T’o fẹrẹ b’angẹl kọrin,
    T’ y’o ró l’ọrun titi,
    Yìn, ará, yìn. Amin.