- mf Mura ẹbẹ, ọkàn mi,
Jesu nfẹ gb’ adura rẹ;
O ti pe k’ o gbadurà,
Nitorina yio gbọ́.
- Lọdọ Ọba n’ iwọ mbọ̀,
Wá lọpọlọpọ ẹ̀bẹ;
Bẹ l’ ore-ọfẹ Rẹ̀ pọ̀,
Kò s’ ẹni ti bère ju.
- mp Mo t’ ibi ẹrù bẹrẹ;
Gbà mi ni ẹrù ẹṣẹ!
di Ki ẹjẹ t’O ta silẹ,
p Wẹ ẹbi ọkàn mi nù.
- Sọdọ̀ Rẹ mo wá simi,
Oluwa, gba aiya mi;
Nibẹ ni ki O jokò,
Ma jẹ oba ọkàn mi.
- N’ irin ajò mi l’aiye,
K’ ifẹ Rẹ ma tù mi n’nu;
Bi ọrẹ at’ oluṣọ,
Mu mi dopin irin mi.
- F’ohun mo ni ṣe hàn mi,
Fun mi l’ ọtun ilera;
Mu mi wà ninu ‘gbagbọ,
Mu mi kú b’ enia Rẹ. Amin.