- f Paṣẹ ‘bukun Rẹ t’oke wá,
Ọlọrun, s’ ara Ijọ yi;
mf Fi ifẹ ti Baba wó wa,
p Gbat’ a f’ ẹ̀ru gboju soke.
- mf Paṣẹ Ibukun Rẹ, Jesum
K’ a lè ṣe ọmọ ẹhin Rẹ;
Sọrọ ipa s’ ọkàn gbogbo,
p Sọ f’ alailera, tẹle mi.
- mf Paṣẹ ‘bukun l’ akoko yi,
Ẹmi otọ, kún ibi yi;
mf F’ agbara iwosàn Rẹ́ kun,
At’ ore-ọfẹ isọji. Amin.