Hymn 536: Jesus, where'er Thy people meet

Jesu, nib’ eni Re pade

  1. f Jesu, nib’ ẹni Rẹ pade,
    Nibẹ, nwọn r’itẹ anu Rẹ;
    Nibẹ, nwọn wa Ọ, nwọn ri Ọ,
    Ibikibi n’ilẹ ọ̀wọ.

  2. mf Kò s’ ogiri t’o sé Ọ mọ́,
    O ngbe inu onirẹlẹ̀;
    Nwọn nmu Ọ wá bi nwọn ba wa,
    Gba nwọn nlọ ‘le, nwọn mu Ọ lọ.

  3. mf Oluṣagután ẹni Rẹ,
    Sọ anu Rẹ ‘gbani d’ọtun;
    cr Sọ adùn orukọ nla Rẹ
    Fun ọkàn ti nwá oju Rẹ.

  4. mf Jẹ k’a r’ipa adua nihin,
    Lati sọ ‘gbagbọ di lilẹ,
    Lati gbe ifẹ wa soke,
    Lati gb’ ọrun kà ‘waju wa.

  5. cr Oluwa, ‘Wọ wá nitosi,
    N’ apá Rẹ, de ‘ti Rẹ silẹ;
    Ṣi ọrun, sọkalẹ kánkán,
    Ṣe gbogbo ọkàn ni Tirẹ. Amin.