- mf Sa wò itẹ anu !
Ọrọ Rẹ̀ pè mi wa
Nibẹ Jesu f’ oju ‘re hàn,
Lati gbọ́ adurà.
- p Ẹjẹ etutu nì,
Ti a ti ta silẹ̀;
Pesè ẹ̀bẹ̀ t’o lè bori,
F’ awọn t’o nt’ Ọlọrun.
- Ifẹ Rẹ̀ lè fun mi
Jù bi mo ti fẹ lọ;
A ma fun ẹnit’o berè
Jù bi nwọn ti nfẹ lọ.
- f Fun wa l’aworan Rẹ,
At’ oju rere Rẹ;
Jẹ ki nlè sìn Ọ nihinyi,
Ki mba lè ba Ọ gbe. Amin.