- Oluwa, ‘Wọ ki o si gba,
Ẹni oṣi b’ emi,
K’ emi lè sunmọ itẹ́ Rẹ,
Ki nke Abba, Baba?
- Jesu, jọwọ fi ọ̀rọ Rẹ
S’okùnkun mi d’ọsan;
Ki gbogbo ayọ tun pada,
Ti mo f’ẹ̀ṣẹ gbọ̀n nù.
- Oluwa mo f’iyanu sin,
Ore Rẹ tobi ju;
Pa mi mọ ninu ifẹ Rẹ,
K’emi má d’ẹṣẹ mọ. Amin.