- mf Oluwa, a wa ‘dọ̀ Rẹ,
L’ ẹsẹ Rẹ l’a kunlẹ̀ si;
A ! ma kẹgàn ẹbẹ̀ wa,
A o wa Ọ lasan bi?
- L’ ọnà ti O yàn fun wa,
L’ a nwá Ọ lọwọlọwọ;
Oluwa, a kì o lọ,
Titi ‘Wọ o bukun wa.
- Ranṣẹ lat’ ọ̀rọ Rẹ wá,
Ti o fi ayọ̀ fun wa;
Jẹ ki Ẹmi Rẹ k’o fun
Ọkàn wa ni igbala.
- Jẹ k’ a wá, k’a si ri Ọ
Ni Ọlọrun Olore;
W’ alaisàn, dá ‘gbekun si,
Ki gbogbo wa yọ si Ọ. Amin.