- mf Oluwa, mo de ‘bi ‘tẹ Rẹ,
Nibiti anu pọ̀ !
Mo fẹ dariji ẹ̀ṣẹ mi,
K’o mu ọkàn mi dá.
- Oluwa, kò yẹ k’ emi sọ
Ohun ti mba berè;
O ti mọ̀ k’ emi to berè,
Ohun ti emi fẹ.
- p Oluwa, mo tọrọ anu,
Eyiyi l’opin na;
Oluwa, anu l’o yẹ mi,
Jẹ ki anu Rẹ wá. Amin.