Hymn 53: The Lord of might, from Sinai’s brow

Oluwa agbara fohun

  1. f Oluwa agbara fọhùn,
    Bi ará l’oke Sinai;
    Awọn Israeli gbohùn Rẹ̀,
    Nwọn si gbọ̀n fun iberu:
    Okunkun ṣú biribiri;
    Ati l’ọtun ati l’osì,
    ff Awọn apata nfaya.

  2. p Oluwa ifẹ jẹ ‘rora
    L’ori oke Kalfari;
    O gbe oju soke ọrun,
    L’ akoko wahala Rẹ̀:
    Fun wa l’o rù ẹrù egbé,
    Fun wa l’o t’ ẹjẹ Rẹ̀ silẹ,
    T’ o si tù Baba l’oju.

  3. mf Ọba ifẹ at’ agbara,
    Oluwa ẹda gbogbo
    cr O npada bọ ninu ogo,
    Lati wa gba ijọba;
    ff Ipè y’o dùn, angẹl y’o hó,
    Halleluya y’o j’orin wọn
    L’ ori Eṣu ati’ iku. Amin.