f Jesu Oluwa ni ‘ṣe Ipilẹ Ijọ Rẹ̀ ; Omi ati ọrọ̀ Rẹ̀, Ni On sì fi tun da; di O t’ ọrun wa, O fi ṣe Iyawo mimọ Rẹ̀; p Ẹjẹ Rẹ̀ l’O si fi ra, Ti O si ku fun u.
mf N’ilẹ gbogbo l’a ṣà wọn, Ṣugbọn nwọn jẹ ọ̀kan; Oluwa kan, ‘gbagbọ kan, Ati baptisi kan; Orukọ kan ni nwọn nyìn, Onjẹ kan ni nwọn njẹ; Opin kan ni nwọn nlepa, Nipa ore-ọfẹ.
mp Bi aiye tilẹe nkẹgàn, Gbat’ iyọnu de ba; B’ija on ẹkọ́-kẹ-kọ Ba mu iyapa wa; cr Awọn mimọ y’o ma ke Wipe, “Y’o ti pẹ to?” p Oru ẹkun fẹrẹ̀ di f Orọ̀ orin ayọ̀.
mf L’arin gbogbo ‘banujẹ, At’ iyọnu aiye, O nreti ọjọ ‘kẹhìn Alafia lailai; cr Titi y’o f’oju rẹ̀ ri, Iran ologo na, f Ti ijọ nla aṣẹgun, p Y’o d’ijọ ti nsimi.
mf L’aiye, yi o ni ‘dapọ̀ Pẹlu Mẹtalọkan ! p O sì ni ‘dapọ̀ didùn Pẹl’ awọn t’o ti sùn; cr A ! alabukun mimọ́! Oluwa, fi fun wa, K’ a ba le ri bi awọn, f K’ a ba Ọ gbe l’ọrun. Amin.