- f Gbogbo enyin ti ngbe aiye,
Ẹ f’ayọ̀ kọorin s’Oluwa;
F’ ibẹru sin, ẹ yin l’ogo,
Ẹ wa s’ọdọ Rẹ̀, k’ ẹ si yọ̀.
- Oluwa, On ni Ọlọrun,
Laisi ‘ranwọ wa, O dá wa;
Agbo Rẹ̀ ni wa, O mbọ́ wa:
O si fi wa ṣ’agutan Rẹ̀.
- Njẹ, f’iyìn wọ ile Rẹ̀ wa,
F’ ayọ̀ sunmọ àgbalá Rẹ̀;
Yin, k’ẹ bukun orukọ Rẹ̀,
Tori o yẹ bẹ lati ṣe.
- Eṣe ! Rere l’ Ọlọrun wa,
Anu Rẹ̀, o wà titi lai;
Otọ Rẹ̀ kò figbakan yẹ̀,
O duro lat’ iran-de-ran. Amin.