- f Ọlọrun, awa fẹ
Ile t’ọla Rẹ wà;
Ayọ̀ ibugbe Rẹ
Ju gbogbo ayọ̀ lọ.
- mf Ile adurà ni,
Fun awa ọmọ Rẹ;
Jesu, O wà nibẹ̀,
Lati gbọ ẹbẹ wa.
- Awa fẹ àse Rẹ,
Kil’ o dùn to l’aiye;
Nib’ awọn olotọ,
Nri Ọ nitosi wọn.
- Awa fẹ ọ̀rọ Rẹ,
Ọrọ Alafia;
T’itunu at’ ìye,
Ọrọ ayọ titi.
- f A fẹ kọrin anú,
T’a nri gbà l’aiye yi;
cr Ṣugbọn awa fẹ mọ̀
Orin ayọ̀ t’ọrun.
- Jesu, Oluwa wa,
mp Busi ‘fẹ wa nihin;
f Mu wa de ‘nu ogo,
Lati yìn Ọ titi. Amin.