Hymn 526: Jesus Thy service bestow

Isin Jesu ni ’funni

  1. mf Isin Jesu ni ‘funni
    L’ayọ̀ totọ, l’aiye yi;
    Isin Jesu ni ‘funni
    mp N’ itunnu ninu iku

  2. Lẹhin ‘ku, ayọ̀ na mbẹ,
    Ti kò ni d’opin lailai;
    f K’ Ọlọrun sa jẹ t’emi,
    cr Ayọ̀ mi kì o l’opin. Amin