Hymn 525: Brother, thou art/ gone be-/fore us,

Ara, iwo si| waju wa lo

  1. mp Ará, iwọ ṣi |waju wa lọ,
    Ẹmi rẹ mi | mọ́ sì ti fò lọ,
    Sibiti kò ni | s’ ẹkun mọ;
    Ti | kò si irora.

  2. O bọ́ lọwọ | ẹrù ara ---
    Ati lọwọ | aniyàn aiye:
    di Nib’ ẹni-buburu | ye yọnu,
    p Ti a|larẹ̀ si simi.

  3. mp ‘Wọ ti rìn ajò | aiye ja,
    O ti | gb’ agbelebu rẹ;
    cr Krist ti fi ẹsẹ rẹ | le ọnà,
    Lati | de ib’ isimi.

  4. mp Bi Lasaru | l’o si sùn,
    L’ a|kaiya Baba rẹ,
    di Nib ẹni-buburu |ye yọnu,
    p Ti a|larẹ̀ si simi.

  5. mf Ẹṣẹ kò le | bà ọ jẹ́ mọ,
    I|yemeji d’ opin;
    Igbagbọ rẹ ni|nu Kristi
    At’ Ẹmi | kò ni yẹ̀ mọ lai.

  6. L’ ọrun lọhun | n’ iwọ o bá
    Awọn ọrẹ́ | t’o ti lọ ṣaju;
    di Nib’ ẹni-buburu | ye yọnu,
    p Ti a|larẹ si simi.

  7. Alufa ti wi ni|sisiyi pe,
    mp Eru f’eru, e|rupẹ̀ f’erupẹ;
    Awa si ko e|rupẹ̀ bò ọ,
    A si | samì s’orì rẹ.

  8. cr Ṣugbọn ẹmi rẹ | ti fò lọ,
    Sọ|dọ awọn mimọ;
    di Nib’ ẹni-buburu | ye yọnu,
    p Ti a|arẹ̀ si simi.

  9. mf ‘Gbat’ Olu|wa ba si pè
    A|wa t’o kù lẹhin;
    Oluwa wa, | awa bẹ̀ Ọ,
    K’ai|ye má bà jẹ,

  10. K’ olukuluku wa, b’ a|rá wa yi,
    Le ri | àye lọdọ Rẹ,
    di Nib’ ẹni-buburu | ye yọnu,
    p Ti a|arẹ̀ si simi. Amin.