mp Awa ti gbe ọ sin, niwọ̀n l’ao daro rẹ, B’o tilẹ̀ jẹ nin’ okunkun l’a sin ọ si; di Jesu rẹ ti là ọnà kanna kọja, Fitilà ifẹ Rẹ̀ ni y’o ma ṣaju rẹ.
mp Awa ti gbe ọ sin, oju wa kò ri ọ mọ, O kò si tun ba wa rìn laiye yi mọ; di Ṣugbọn Jesu ti n’ apa ifẹ Rẹ̀ si ọ, p Nj’ ẹlẹṣẹ lè kú, nitori Jesu ti kú.
mp Awa ti gbe ọ sin, o ti bọ́ agọ rẹ silẹ̀, Bọya ẹs’ ẹmí rẹ kọ́lẹ̀ lati lọ; f Ṣugbọn iwọ ti ji s’imọlẹ Paradise, ‘Wọ si ti ngbọ orin awọn Serafu.
mp Awa ti gbe ọ sin, niwọ̀n l’a o daro rẹ, Ọlọrun rẹ li Olurapada rẹ, f O gba ọ lọwọ wa, y’o si ji ọ dide, Ikú kò n’ oro mọ, ‘tori Jesu ti kú. Amin.