- p Itana t’o bò ‘gbe l’ aṣọ,
T’o tutù yọyọ be;
cr Gba doje ba kan, a si kú,
A ṣubu, a si rọ.
- Apẹrẹ yi yẹ f’ara wa,
B’ọr’ Ọlọrun ti wi;
K’ọmọde at’ agbalagba
p Mọ̀ ‘ra wọn l’eweko.
- p A ! má gbẹkẹle ẹ̀mi rẹ,
Má pè ‘gba rẹ ntirẹ;
cr Yika l’a nri doje ikú,
O mbẹ́ ‘gberun lulẹ̀.
- Ẹnyin t’a dasi di oni,
p Laipẹ, ẹmí y’o pin,
Mura k’ẹ si gbọ́n l’akoko,
K’ ikọ̀ ikú to de.
- Koriko, b’o kú, ki ji mọ;
Ẹ kù lati tun yè;
p A ! b’ iku lọ jẹ ‘lẹkun nkọ
S’ irora ailopin !
- f Oluwa, jẹ́ k’a jipé Rẹ,
K’a kuro n’nu ẹ̀ṣẹ;
Gbat’ a lulẹ̀ bi koriko,
K’ ọkàn wa yọ si Ọ. Amin.