- mp Ọdun nyipo, o nji emi,
T’O ti fi fun wa ri,
Ibikibi t’o wù k’a wà,
p Isà okú l’ a nrè.
- Yi ilẹ ka l’ ewu duro,
K’ o lè tì wa s’ isà;
Arun buburu si duro,
Lati le wa lọ ‘le.
- mp Ayọ̀ tab’ egbe ailopin,
Duro de ẹmi wa;
Wo ! b’ a ti nrin l’ aibikità,
Leti bèbe ikú.
- f Oluwa, ji wa l’ orun wa,
K’a r’ ọ̀na ewu yi;
Nigbat’ a ba pe ọkàn wa,
K’a ba Ọ gbe titi. Amin.