Hymn 520: The saints of God! their conflict past

Awon mimo, lala pari

  1. mf Awọn mimọ, lala pari,
    Nwọn ti jà, nwọn si ti ṣẹgun,
    Nwọn kò fẹ ohun ìja mọ,
    Nwọn dà wọn ‘lẹ̀ l’ ẹsẹ Jesu:
    cr A ! ẹnyin ẹni ibukun,
    p Isimi nyin ti daju to !

  2. mf Awọn mimọ, ìrin pari,
    Nwọn kò tun sure ije mọ,
    Arẹ at’ iṣubu d’ opin,
    Ọtá on ẹ̀ru kò sí mọ:
    cr A ! ẹnyin ẹni ibukun,
    p Isimi nyin ti daju to !

  3. mf Awọn mimọ, àjo pari,
    Nwọn ti gún s’ ilẹ ibukun,
    Iji kò dẹruba wọn mọ,
    Igbi omi kò n’ ipá mọ;
    cr A ! ẹnyin ẹni ibukun,
    p Isimi nyin ti daju to !

  4. Awọn mimọ, oku wọn sùn
    Ninu ilẹ, awọn nṣọnà
    cr Titi nwọn yio fi jinde,
    Lati fi ayọ goke lọ:
    f A ! ẹni ‘bukun, ẹ kọrin;
    Oluwa at’ Ọba nyin mbọ̀.

  5. mf Ọlọrun wọn, ‘Wọ l’a nkepè,
    Jesu, bẹ̀bẹ fun wa l’ oke;
    Ẹmi Mimọm Olutọ́ wa,
    p F’ ore-ọfẹ fun wa d’ opin;
    cr K’a le b’ awọn mimọ simi,
    f Ni Paradise pẹlu Rẹ. Amin.