Hymn 52: The Church has waited long

Ijo ti nduro pe

  1. mp Ijọ ti nduro pẹ
    Lati ri Oluwa:
    O sì wà bakanna sibẹ
    Kò s’ alabarò fun !
    Ọdun nyí lu ọdun,
    Ọjọ ngori ọjọ,
    Sibẹ lairi Oluwa rẹ̀,
    O wà ninu ọ̀fọ:
    Ma bọ̀, Jesu, ma bọ̀!

  2. mp Awọn mimọ laiye
    Ọpọ wọn l’o ti ku;
    p Bi nwọn si tí nlọ l’ọkọkan,
    A tẹ́ wọn lati sùn
    Ki ṣe l’ ainireti;
    cr A tẹ́ wọn lati rẹju ni
    K’ ilẹ ogo to mọ.
    Ma bọ̀, Jesu, ma bọ!

  3. mp Awọn ọta npò sí;
    Agbara Eṣu nga;
    Ogun ngbona, igbagbọ nku,
    Ifẹ si di tutu.
    cr Y’ o ti pẹ tó! Baba
    Olotọ, Olore!
    ‘Wọ ki y’o kọ̀ya omije
    At’ ẹjẹ Ijọ Rẹ?
    f Ma bọ̀, Jesu, ma bọ̀.

  4. mf A nfẹ gbọ ohùn Rẹ,
    A nfẹ f’oju kàn Ọ;
    K’ a le gbá ade at’ ogo
    B’a ti ngbá ore Rẹ.
    f Jọ, wá m’ẹṣẹ kuro
    At’ ègún at’ èri,
    K’ o si sọ aiye òṣi yi
    D’ aiye rere Tirẹ,
    Ma bọ̀, Jesu, ma bọ̀. Amin.