mp “’Ranṣẹ Ọlọrun, ṣeun; Simi n’nu lala rẹ; mf Iwọ ti jà, o sì ṣẹgun; Bọ́ s’ ayọ Baba rẹ.” Ohùn na de loru, O dide lati gbọ; p Ọfa iku si wọ l’ ara, pp O ṣubu, kò bẹ̀ru.
f Igbe ta lọganjọ, “Pade Ọlọrun rẹ.” O ji, o ri Balogun rè; N’n’ adurà on ‘gbagbọ, --- cr Ọkan rẹ nde wìri, O bọ́ amọ̀ silẹ, Gbat’ ilẹ mọ, agọ ara p Sì sùn silẹ l’ oku.
f ‘Rora iku kọja, Lala at’ ìṣẹ́ tán: Ọjọ ogun jàja pari, Ọkàn rẹ̀ r’ alafia; f Ọmọ-gun Krist’, o ṣeun ! Ma kọrin ayọ̀ ṣa ! ff Simi lọdọ Olugbala, cr Simi titi aiye. Amin.