Hymn 518: Now the laborer’s task is o’er;

Lala alagbase tan

  1. mp Lala alagbṣe tan;
    Ọjọ ogun ti pari;
    cr L’ ebute jijìn réré
    Ni ọkọ̀ rẹ̀ ti gùn si:
    p Baba, labẹ itọju Rẹ,
    L’ awa f’ iranṣẹ Rẹ yi si.

  2. mf Nibẹ l’a rẹ’ wọn l’ẹkún;
    Nibẹ, nwọn m’ ohun gbogbo;
    di Nibẹ l’ Onidaj’ otọ
    Nda iṣẹ aiye wọn wò.
    p Baba, labẹ, &c.

  3. mf Nibẹ l’ oluṣ’ agùtan
    Nko awọn agutan lọ;
    di Nibẹ̀ l’ o ndabòbo wọn,
    Kòríkò ko le de ‘bẹ̀.
    p Baba, labẹ, &c.

  4. mp Nibẹ̀ l’ awọn ẹlẹṣẹ,
    Ti ntẹju m’ agbelebu,
    cr Y’o mọ̀ ifẹ Kristi tan,
    L’ẹsẹ Rẹ̀ ni Paradis,
    p Baba, labẹ, &c.

  5. mf Nibẹ l’ agbara Eṣu
    Kò le b’ ayọ̀ wọn jẹ mọ;
    Kristi Jesu sa nṣọ wọn,
    On t’o ku fun ‘dane wọn.
    p Baba, labẹ, &c.

  6. pp “Erupè fun erupe,”
    L’ ède wa nisisiyi;
    A tẹ silẹ lati sùn
    cr Titi d’ọjọ ajinde.
    p Baba, labẹ, &c. Amin.