- mp Bi agogo ọ̀fọ t’ a nlu,
Ti npè ọkàn yi kọja lọ,
K’ olukuluku bi ‘r rẹ̀,
“Mo ha ṣetan b’ iku pè mi?”
- mp “Ki nf’ ohun ti mo fẹ silẹ,
Ki nlọ sid’ itẹ iddajọ?
Ki ngbohùn Onidajọ na,
Ti y’o sọ ipò mi fun mi.”
- p Ara mi ha gba, b’ o wipe,
“Lọ lọdọ mi eni egùn?”
cr Sinu ina t’ a ti pèse
Fun Eṣu ati ogun rẹ̀?”
- f Jesu Oluwa, jọ gbà mi,
Iwọ, ni mo gbẹkẹ mi le;
Kọ́ mi ki nr’ ọ̀na ewu yi,
Kọ́ mi ki mba Ọ gbe titi. Amin.