Hymn 516: How sweet the hour of closing day

Igba asale ti dun to

  1. mp Igba aṣalẹ ti dùn to !
    Ti ara tù ohun gbogbo:
    ‘Gbat’ ìtanṣan orùn alẹ
    Ba ntànmọlẹ s’ ohun gbogbo!

  2. Bẹni ‘kẹhìn onigbagbọ,
    On a simi l’ alafia;
    cr Igbagbọ to gbona janjan
    A mọlẹ ninu ọkàn rẹ̀.

  3. mf Imọlẹ kan mọ loju rẹ̀,
    Ẹrin sì bọ ni ẹnu rẹ̀;
    O nf’ ède t’ ahọn wa kò mọ̀
    Sọ̀rọ ogo t’o sunmọle.

  4. cr Itanṣan ‘mọlẹ t’ ọrun wá,
    Lati gba niyanju lọna;
    Awọn angẹl duro yika
    Lati gbe lọ s’ibugbe wọn.

  5. mp Oluwa, jẹ k’ a lọ bayi,
    K’a ba Ọ yọ̀, k’a r’ oju Rẹ;
    cr Tẹ̀ aworan Rẹ s’ ọkàn wa,
    Si kọ́ wa b’ a ti ba Ọ rìn. Amin.