- mf A ! nwọn ti gún s’ ebute,
p Loke ọrun; Loke ọrun;
mf Ebi kò ni pa wọn mọ,
Nwọn bọ lọwọ irora,
f Loke ọrun; Loke ọrun;
- A ! nwọn kò wa fitilà,
p Loke ọrun; Loke ọrun;
‘Mọlẹ̀ ni l’ọjọ gbogbo,
Jesu si n’ Imọlẹ wọn,
f Loke ọrun; Loke ọrun;
- A ! wura n’ ita wọn jẹ,
p Loke ọrun; Loke ọrun;
Ogo ‘bẹ si pọ̀ pupọ,
Agbo Jesu ni nwọn jẹ
f Loke ọrun; Loke ọrun;
- A ! otutu ki mu wọn,
p Loke ọrun; Loke ọrun;
Oworẹ́ wọn ti kọja,
Gbogbo ọjọ l’o dara;
f Loke ọrun; Loke ọrun;
- A ! nwọn ckun ìja ‘ja,
p Loke ọrun; Loke ọrun;
Jesu l’ o ti gbà wọn là,
T’ awọn Tirẹ l’ o sì nrìn,
Loke ọrun; Loke ọrun;
- A ! nwọn kò ni sọkun mọ,
p Loke ọrun; Loke ọrun;
Jesu sa wà lọdọ wọn,
Lọdọ Rẹ̀ ni ayọ̀ wà,
f Loke ọrun; Loke ọrun.
- A ! a o dapọ mọ wọn,
p Loke ọrun; Loke ọrun;
A nreti akoko wa,
f ‘Gba Oluwa ba pè ni
di S’ oke ọrun; S’ oke ọrun. Amin.