- p Gbat’ a kún fun banujẹ,
Gb’ omije nṣàn loju wa;
Gbat’ a nsọkun, t’a nṣọ̀fọ,
cr Olugbala, gbọ ti wa.
- p ‘Wọ ti gbe ara wa wọ̀;
O si mọ̀ banujẹ wa;
O ti sọkun bi awa,
cr Olugbala, gbọ ti wa.
- pp ‘Wọ ti tẹriba fun ‘ku;
‘Wọ ti t’ ẹjẹ Rẹ silẹ;
A tẹ́ Ọ si posi ri;
cr Olugbala, gbọ ti wa.
- Gbat’ ọkàn wa ba bajẹ,
Nitori ẹṣẹ t’a da;
Gbat’ ẹ̀ru ba b’ọkàn wa,
cr Olugbala, gbọ ti wa.
- p ‘Wọ ti mọ̀ ẹrù ẹṣẹ,
Ẹṣẹ ti ki ‘ ṣe Tirẹ:
Ẹru ẹṣẹ na l’O gbe,
cr Olugbala, gbọ ti wa.
- f O ti ṣilẹkun iku,
O ti ṣ’etutu f’ ẹṣẹ;
ff O wà lọw’ ọtun Baba,
di Olugbala, gbọ ti wa. Amin.