- mp Isimi wa l’ọrun, kò si l’aiye yi,
Emi o ṣe kun, gbati ‘yọnu ba de;
Simi, ọkàn mi, eyikeyi t’o de,
O din ajò mi kù, o mu k’ile ya.
- Ko tọ fun mi, ki nma simi nihinyi,
Ki nsì ma kọle mi ninu aiye yi;
Ongbẹ ilu t’a kò f’ ọwọ kọ ngbẹ mi,
Mo nreti aiye ti ẹ̀ṣẹ kò bajẹ.
- Ẹgún èṣuṣu lè ma hù yi mi ka,
Ṣugbọn emi kò ni gbera le aiye;
Emi kò wá isimi kan ni aiye,
Tit’ em’ o fi simi l’ aiya Jesu mi.
- ‘Yọnu lè damu, ṣugbọn kò lè pa mi,
Oju ‘fẹ Jesu lè sọ ‘yọnu d’ẹrín,
Ẹrin Rẹ̀ lè sọ ẹkun wa di ayọ̀,
B’ igbà t’ ẹfufu fẹ òjo ṣiṣu lọ. Amin.