Hymn 51: That day of wrath, that dreadful day

Ojo ’binu, ojo eru

  1. f Ọjọ ‘binu, ọjọ ẹ̀ru
    T’ aiye at’ ọrun y’ o folọ,
    di Kin’ igbẹkẹle ẹlẹṣẹ?
    p Y’ o ṣe le yọju l’ ọjọ na?

  2. f Nigbati ọrun y’o kakò
    Bi awọ ti a f’ ina sun;
    cr T’ ipè ajinde o ma dùn
    ff Kikankikan, tẹ̀rutẹ̀ru.

  3. p A! l’ọjọ na, ọjọ ‘binu,
    T’ ẹda yio ji si ‘dajọ,
    cr Kristi, jọ ṣe ‘gbẹkẹle wa
    di ‘Gba t’aiye t’ọrun ba fòlọ. Amin.