- mp O ṣ’ ohun t’o tì mi loju,
Pe, nigba kan l’aiye mi,
p Olugbala nkanu lasan,
O npè mi, mo si ndahun pe,
“T’ emi ṣa, nkò náni Rẹ.”
- Ṣugbọn O ri mi; mo si wo
L’ or’ igi agbelebu;
Mo si gbọ́, “Fijì wọn Baba,”
Ọkàn mi f’ inira wipe,
“Em’ o nàni Rẹ diẹ.”
- p Lojojumọ li anu Rẹ̀
Nṣe ‘wosàn fun ọkàn mi,
f Agbara at’ ifẹ l’ O fi
Nfa mi mọra, mo si wipe,
“Ngo náni Rẹ diẹ si.”
- f Ifẹ Rẹ ga jù ọrun lọ,
O si jìn jù okun lọ;
Ifẹ Rẹ na l’ o ṣẹgun mi,
Jẹ ki nlè wi nitotọ pe,
“Em’ o wa fun Ọ titi.” Amin.