mp A fẹ ri Jesu, ‘tori ojiji wa ngùn, Ojiji igba ọjọ aiye wa; A fẹ ri Jesu, k’O busi gbàgbọ wa, Nigbà akókò titan wa ba de.
A fẹ ri Jesu, arẹ nmu ọkàn wa, A fẹ ri I, arẹ nmu ara wa; Igbì iyọnu pupọ̀ l’o ti nlù wa, Igbì mi sì tun ndide tọ wa bọ̀.
cr A fẹ ri Jesu, Apata ‘pilẹ̀ wa, Li ori eyiti a duro le; f Iyè, iku, gbogbo wahala aiye, Kò lè y’ ẹsẹ̀ wa, b’ a ba roju Rẹ̀.
mp A fẹ ri Jesu, aiye kò l’adùn mọ. Ohun t’a nyọ̀ si ri ṣá l’oju wa, di Awọn ọrẹ́ wa gbogbo l’o ti nkọja lọ, cr Ao kẹdùn wọn mọ, ṣe awa na mbọ̀.
p A fẹ ri Jesu, ṣugbọn oju nro wa, Nitori awọn ará at’ ọrẹ́; Ara wa pẹlu kò fẹ f’aiye silẹ̀, Ifẹ wa si Ọ kò mu ‘fẹ yi dinkù.
p A fẹ ri Jesu, oju ọkàn wa fọ́, Ọrun ṣú, o sì jinà loju wa; cr A fẹ ri Ọ, O rán ọkàn wa leti Iyà t’O jẹ lati san gbeṣe wa.
f A fẹ ri Jesu, eyi l’ohun t’a fẹ, Gbà t’a ba ri Ọ, ayọ̀ nla y’o de; ‘Wọ t’Oku, t’O jinde, t’O mbẹ̀bẹ̀ fun wa, ff ‘Gbana, ‘mọlẹ y’o de, okùn y’o si lọ. Amin.