Hymn 507: Thou art my hiding-place, O Lord

Jesu ’Wo n’ ibi sadi mi

  1. mf Jesu, ‘Wọ n’ ibi sadi mi,
    ‘Wọ ni mo gbẹkẹle;
    Ọrọ Rẹ n’ iranlọwọ mi,
    Emi alailera.
    di Nkò ni ẹjọ kan lati rò,
    Kò s’ohun ti ngo wi;
    p Eyi to, pe Jesu mi kú,
    Jesu mi kú fun mi.

  2. mf Igba ìji ‘danwo ba njà,
    T’ ọta ndojukọ mi,
    Itẹ anu n’ isadi mi,
    Nibẹ n’ ireti mi.
    Ọkàn mi yio sá tọ wa,
    p ‘Gba ‘banujẹ ba de;
    cr Ayọ ọkàn mi l’eyi pe,
    p Jesu mi kú fun mi.

  3. mp Larin iyọnu t’o wuwo,
    T’enia kò lè gbà;
    Larin ibanujẹ ọkàn,
    Ati ‘rora ara;
    Kil’ o lè funni n’ isimi,
    Ati suru b’eyi?
    T’o nṣ’ ẹlẹri l’ọkàn mi pe,
    p Jesu mi kú fun mi.

  4. pp ‘Gba ohùn Rẹ ba si paṣẹ
    K’ ara yi dibaje,
    Ti ẹmi mi, b’ iṣàn omi,
    Ba si ṣàn kọja lọ,
    cr B’ ohùn mi kò tilẹ jalẹ,
    Nigbana, Oluwa,
    mf Fun mi n’ ipa ki nle wipe,
    p Jesu mi kú fun mi. Amin.