- mf Ọlọrun mi, ‘Wọ l’ em’ o pè;
p Ara nni mi, gbọ́ igbe mi:
cr ‘Gba ‘ṣàn omi ba bori mi,
Má jẹ k’ ọkàn mi fasẹhìn.
- Iwọ Ọrẹ́ alailera,
Tani mba ṣ’ aroye mi fun?
Bikoṣe ‘Wọ nikanṣoṣo,
T’ O npè otoṣi w’ ọdọ Rẹ?
- p Tal’ o sọkun tọ lasan ri?
‘Wọ kọ igbe ẹnikan ri?
Ṣe Iwọ ni O ti sọ pe,
Ẹnikan k’yo wá Ọ lasan?
- p Eyi ‘ba jẹ ‘binujẹ mi
Pe, O kò ndahun adurà;
Ṣugbọn ‘Wọ ti ngbọ́ adurà,
Iwọ l’O nṣe ìranwọ mi.
- Mo mọ̀ pe alaini l’emi,
Ọlọrun kò ni gbagbe mi;
Ẹniti Jesu mbẹbẹ fun,
O bọ lọwọ gbogbo ‘yọnu. Amin.