- mp Simi le Oluwa -- ẹ gbọ
Orin durù ọrun ---
cr Simi le ‘fẹ Rẹ̀ ailopin,
p Si duro jẹ.
- mf Simi, iwọ ọkọ t’ o gba
Iyawo rẹ loni;
Ninu Jesu, ‘yawo rẹ ni
Titi aiye.
- mp Iwọ ti a fà ọwọ rẹ
F’ọkọ n’nu ile yi,
Simi; Baba f’edidi Rẹ̀
S’ileri nyin.
- mf Ẹ simi, ẹnyin ọ̀rẹ wọn,
T’ẹ wa ba wọn pèjọ;
Ọlọrun wọn ati ti nyin
Gbà ohùn wọn.
- Simi, Jesu Ọkọ Ijọ
Duro ti nyin nihin;
Ninu idapọ̀ nyin, O nfà
p Ijọ mọra.
- mp Ẹ simi :--- Adaba Mimọ,
M’ ọrọ̀ Rẹ ṣẹ n’nu wa----
cr Simi le ‘fẹ Rẹ̀ ailopin,
p Si duro jẹ. Amin.