- Jesu f’ ara han nitotọ,
Nibi àse ‘yàwo;
Oluwa, awa bẹ̀ Ọ, wá,
F’ ara Rẹ hàn nihin.
- Fi ibukun Rẹ fun awọn
Ti o dawọpọ̀ yi;
F’ ojurere wò ‘dàpọ wọn,
Si bukun ẹgbẹ wọn.
- F’ ẹbun ifẹ kún aiya wọn,
Fun wọn n’ itẹlọrùn;
Fi alafia Rẹ kùn wọn,
Si busi ini wọn,
- F’ ifẹ mimọ́ sọ wọn d’ ọ̀kan,
Ki nwọn f’ ifẹ Kristi
Mú aniyan ile fẹrẹ̀,
Nipa ajumọ̀ṣe.
- Jẹ ki nwọn ràn ‘ra wọn lọwọ,
Ninu igbagbọ wọn;
Ki nwọn si ni ọmọ rere,
Ti y’o gbe ‘le wọn ró! Amin.