- mf Ọlọrun, gb’ ọkàn mi loni,
Sì ma ṣe ni Tirẹ;
Ki mmá ṣako lọdọ Rẹ mọ,
Ki mmá yẹ̀ lọdọ Rẹ.
- p Wo ! mo wólẹ buruburu
cr L’ẹsẹ agbelebu;
Kàn gbogbo ẹ̀ṣẹ mi mọ ‘gi,
Ki Krist’ j’ ohun gbogbo.
- F’ ore-ọfẹ ọrun fun mi,
Sì ṣe mi ni Tirẹ;
Ki nle r’ oju Rẹ t’o logo,
Ki mma sìn n’itẹ Rẹ.
- K’èro, ọ̀rọ, at’ iṣe mi,
Jẹ Tirẹ titi lai;
Ki nfi gbogb’ aiye mi sìn Ọ,
p K’ iku jẹ isimi.
- ff Ogo gbogbo ni fun Baba,
Ogo ni fun Ọmọ,
Ogo ni fun Ẹmi Mimọ,
ff Titi ainipẹkun. Amin.