- f Ji, ọkàn mi, dide gíri,
Ma lepa nṣo kikan:
F’ itara sure ije yi,
Fun ade ti ki ṣá.
- mf Awọsanma ẹlẹri wà,
Ti nwọn nf’ oju sùn Ọ
cr Gbagbe ìrin atẹ̀hinwá,
Sa ma tẹ̀ siwaju.
- f Ọlọrun nf’ ohùn ìgbera
Ké si ọ lat’ òke:
Tikarẹ̀ l’O npin ère na,
T’o nnọ̀ga lati wò.
- mf Olugbala, ‘Wọ l’o mu mi
Bẹ̀rẹ ìje mi yi;
Nigbat’ a ba de mi l’ ade,
Ngo wolẹ lẹsẹ Rẹ. Amin.