Hymn 500: Oh happy day, that fixed my choice

Ojo nla l’ ojo ti mo yan

  1. f Ọjọ nla l’ ọjọ́ ti o yàn
    Olugbala l’Ọlọrun mi:
    O yẹ ki ọkàn mi ma yọ̀,
    K’o sì ro ìhin na ká ‘lẹ̀.
    f Ọjọ nla l’ ọjọ na!
    p Ti Jesu wẹ̀ ẹ̀ṣẹ mi nù;
    O kọ mi ki mma gbadura,
    Ki mma ṣọra, ki nsì ma yọ̀,
    Ọjọ nla l’ ọjọ na!
    Ti Jesu wẹ̀ ẹ̀ṣẹ mi nù.

  2. Iṣẹ ìgbala pari na,
    Mo di t’ Oluwa mi loni;
    On l’o pè mi ti mo sì jẹ́,
    Mo f’ ayọ̀ jipè mimọ ná.
    f Ọjọ nla, &c.

  3. Ẹjẹ́ mimọ yi ni mo jẹ́
    F’ Ẹnit’ o yẹ lati fẹràn;
    Jẹ k’ orin didùn kún ‘le Rẹ̀,
    Nigba mo ba nlọ sìn nibẹ.
    f Ọjọ nla, &c.

  4. Simi, aiduro ọkàn mi,
    Simi le Jesu Oluwa;
    Tani jẹ wipe aiye dùn
    Jù ọ̀dọ awọn Angẹli?
    f Ọjọ nla, &c.

  5. Ẹnyin ọrun, gbọ ẹ̀jẹ́ mi;
    Ẹjẹ́ mi ni ojojumọ,
    Em’ o ma sọ dọtun titi
    Iku y’o fi mu mi re ‘le.
    f Ọjọ nla, &c. Amin.