- f Ọjo ‘dajọ on ‘binu,
Ọjọ ti Jesu pa ni,
Gọngọ a sọ n’ ijọ na!
- ff Kikan n’ ipè o ma dún,
Isa oku yio ṣi,
Gbogbo oku y’o dide.
- mf Iku papa y’o dijì,
Ẹda gbogbo y’o dide
Lati j’ ipè Ọlorun.
- A o ṣi Iwe silẹ,
Ao sì kà ninu rè
p Fun ‘dajọ t’oku t’ayè
- Onidajọ Ododo,
Jọ w’ẹṣẹ mi gbogbo nù
K’ ọjọ ‘ṣiro na to de. Amin.