- mf Wà s’ọdọ mi, Oluwa mi,
Ni kutukutu owurọ’
Mu k’ero rere sọ jade,
Lat’ inu mi soke ọrun.
- Wá s’ọdọ mi Oluwa mi,
Ni wakati ọ̀sán gangan;
Ki ‘yọnu má ba se mi mọ
Nwọn a si s’ọsan mi d’oru.
- mp Wà s’ọdọ mi Oluwa mi,
Nigbati alẹ ba nlẹ lọ;
Bi ọkan mi ba nsako lọ,
Mu pada; f’oju ‘re wò mi.
- Wà s’ọdọ mi Oluwa mi,
Li oru, nigbati orun
p Ko woju mi; jẹ k’ọkan mi
Ri ‘simi jẹ li aiya Rẹ.
- mp Wà s’ọdọ mi Oluwa mi,
Ni gbogbo ọjọ aiye mi;
p Nigbati ẹ̀mi mi ba pin,
f Ki nle n’ ibugbe lọdọ Rẹ. Amin.