Hymn 499: ''Thine ? Thine for ever'' ? blessed bond

Tire titi lai l’ awa se

  1. mf Tirẹ titi lai l’ awa ṣe,
    Oluwa wa ọrun;
    cr K’ ohùn at’ ọkàn wa wipe,
    Amin, bẹni k’ o ri.

  2. mf ‘Gbati aiye ba ndùn mọ ni,
    T’o si nfa ọkàn wa;
    f K’ irò yi pe, “Tirẹ l’ awa,”
    Lè ma dùn l’ eti wa.

  3. mp ‘Gbat’ ẹ̀ṣẹ pẹlu ẹ̀tan rẹ̀,
    Ba fẹ ṣe wa n’ ibi;
    p K’irò yi pe, “Tirẹ l’awa,”
    Tu ẹ̀tan ẹ̀ṣẹ ka.

  4. mf ‘Gbati Eṣu ba ntafà rẹ̀,
    S’ ori ailera wa;
    f K’irò yi pe, “Tirẹ l’awa,”
    Má jẹ ki o rè wa.

  5. mf “Tirẹ,” n’ igb’ a wà l’ọmọde,
    cr “Tirẹ,” n’ igb’ a ndagbà,
    di “Tirẹ,” n’ igb’ a ba darugbo,
    p Ti aiye wa mbuṣe.

  6. ff “Tirẹ” titi lai l’ awa ṣe,
    A f’ ara wa fun Ọ:
    Titi aiye ainipẹkun,
    Amin, bẹni k’o ri. Amin.