mf Mo ti ṣeleri, Jesu, Lati sìn Ọ dopin; Ma wà lọdọ mi titi, Baba mi, Ọrẹ́ mi, Emi k’yo bẹru ogun, B’ iwọ ba sunmọ mi, Emi kì y’o si ṣina, B’o ba f’ọna hàn mi.
Jẹ ki mmọ̀ p’ o sunmọ mi, ‘Tor’ibajẹ aiye; Aiye fẹ gbà ọkàn mi, Aiye fẹ tàn mi jẹ; di Ọta yi mi ka kiri, Lode ati ninu; cr Ṣugbọn Jesu, sunmọ mi, Dabobo ọkàn mi.
p Jẹ ki emi k’o ma gbọ́ Ohùn Rẹ, Jesu mi, Ninu igbi aiye yi, Titi nigbagbogbo; cr Sọ, mu k’o dá mi l’oju, K’ ọkàn mi ni ‘janu; Sọ, si mu mi gbọ Tirẹ, ‘Wọ olutoju mi.
mf ‘Wọ ti ṣe ‘leri, Jesu, F’ awọn t’o tẹ̀le Ọ, Pe ibikibi t’ O wà, L’awọn yio si wà; Mo ti ṣe ‘leri, Jesu, Lati sìn Ọ dopin, Jẹ ki nma tọ Ọ lẹhin, Baba mi, Ọrẹ́ mi.
p Jẹ ki nma ri ‘pasẹ Rẹ, Ki nlè ma tẹlé Ọ: Agbara Rẹ nikan ni, Ti mba lè tẹlé Ọ, Tọ́ mi, pè mi, sì fà mi, Di mi mu de opin; Si gba mi si ọdọ Rẹ. Baba mi, Ọrẹ́ mi. Amin.