- mf Emi o lọ sọdọ Jesu,
Ẹni npè mi pe ki’m wa,
Ẹnit’ o ṣe Olugbala
Fun ẹlẹṣẹ bi emi.
- mf Emi o lọ sọdọ Jesu,
p Irira at’ ibinu,
cr Ikà at’ iṣẹ t’ o buru,
T’enia nṣe, On kò ni.
- mf Emi o lọ sọdọ Jesu,
O dùn mọ mi ki nṣe bẹ;
Tal’ o fẹ mi bi ti Jesu,
Ẹniti o gbà ni là?
- Emi o lọ sọdọ Jesu,
Jesu t’ o ṣe Ọrẹ wa:
Anu wà ninu Rẹ̀ pupọ,
Fun ẹlẹṣẹ bi emi. Amin.