Hymn 496: Lord, shall Thy children come to Thee?

Oluwa, k’ a ha w’ odo Re

  1. mf Oluwa, k’a ha w’ ọdọ Rẹ?
    Ẹbun ọrun ni a ntọrọ;
    mp Nigba ti a wà ni ewe,
    L’a ti gbe wa wá ọdọ Rẹ,
    cr Fun wa ni ore-ọfẹ Rẹ,
    K’ a lè tọ̀ Ọ wá fun ‘ra wa.

  2. mf Oluwa, k’a ha w’ ọdọ Rẹ,
    Nigb’ a ba tẹ tabili Rẹ,
    p T’ a nṣe apẹrẹ ikú Rẹ,
    Ni jij’àkara, mimu wain?
    cr Gb’ adurà awọn ọmọ Rẹ,
    Ki nwọn k’o le ri Ọ nibẹ̀.

  3. mf Oluwa, k’a ha w’ ọdọ Rẹ?
    Ki ṣe nigba yi nikan ni,
    cr Ṣugbọn ni gbogbo ọjọ wa,
    Nigba ọrọ̀ tabi ìṣẹ́
    K’a wa s’ ibi ‘tẹ or’ọfẹ,
    f K’a duro ṣinṣin n’ igbagbọ.

  4. mf Oluwa, k’a ha w’ ọdọ Rẹ?
    A fẹ bere ẹbun kan si;
    Pe, ‘gbati aiye ba kọja,
    Ti ipè ikẹhin ba dùn,
    f K’ a lè w’ọdọ Rẹ, Oluwa,
    K’ a si nipò wa l’aiyà Rẹ. Amin.